Mika 1:13
Micah 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.
Micah 1:13 in English
Micah 1:13 · Berean Standard Bible
Harness your chariot horses, O dweller of Lachish.* You were the beginning of sin to the Daughter of Zion, for the transgressions of Israel were found in you.
Context
11Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,
ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.
Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani
kì yóò sì jáde wá.
Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;
a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin. 12Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre,
ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 13Ìwọ olùgbé Lakiṣi,
dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.
Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀
sí àwọn ọmọbìnrin Sioni,
nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀. 14Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀
fún Moreṣeti Gati.
Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli. 15Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa.
Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli
yóò sì wá sí Adullamu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.