Native Bible

Matthew 9:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.

Matthew 9:24 in English

Matthew 9:24 · Berean Standard Bible

“Go away,” He told them. “The girl is not dead, but asleep.” And they laughed at Him.

Context

22Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà. 23Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. 26Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.