Native Bible

Matthew 9:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.

Matthew 9:22 in English

Matthew 9:22 · Berean Standard Bible

Jesus turned and saw her. “Take courage, daughter,” He said, “your faith has healed you.” And the woman was cured from that very hour.

Context

20Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. 21Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 22Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà. 23Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.