Matiu 9:17
Matthew 9:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”
Matthew 9:17 in English
Matthew 9:17 · Berean Standard Bible
Neither do men pour new wine into old wineskins. If they do, the skins will burst, the wine will spill, and the wineskins will be ruined. Instead, they pour new wine into new wineskins, and both are preserved.”
Context
15Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀. 16“Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.” 18Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” 19Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.