Native Bible

Matthew 9:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

Matthew 9:15 in English

Matthew 9:15 · Berean Standard Bible

Jesus replied, “How can the guests of the bridegroom mourn while He is with them? But the time will come when the bridegroom will be taken from them; then they will fast.

Context

13Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ,’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” 14Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?” 15Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀. 16“Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.