Matiu 8:31
Matthew 8:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”
Matthew 8:31 in English
Matthew 8:31 · Berean Standard Bible
So the demons begged Jesus, “If You drive us out, send us into the herd of pigs.”
Context
29Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?” 30Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn. 31Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.” 32Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi. 33Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí èṣù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.