Native Bible

Matthew 8:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”

Matthew 8:29 in English

Matthew 8:29 · Berean Standard Bible

“What do You want with us, Son of God?” they shouted. “Have You come here to torture us before the appointed time?”

Context

27Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?” 28Nígbà ti ó sì dé apá kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gadara, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀. 29Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?” 30Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn. 31Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.