Native Bible

Matthew 8:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

Matthew 8:21 in English

Matthew 8:21 · Berean Standard Bible

Another of His disciples requested, “Lord, first let me go and bury my father.”

Context

19Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” 20Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.” 21Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.” 22Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.” 23Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.