Matiu 6:13
Matthew 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
Matthew 6:13 in English
Matthew 6:13 · Berean Standard Bible
And lead us not into temptation, but deliver us from the evil one.*’
Context
11Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. 12Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa, 13Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’ 14Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. 15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.