Matiu 5:44
Matthew 5:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.
Matthew 5:44 in English
Matthew 5:44 · Berean Standard Bible
But I tell you, love your enemies and pray for those who persecute you,*
Context
42Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò. 43“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.