Matiu 5:10
Matthew 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.
Matthew 5:10 in English
Matthew 5:10 · Berean Standard Bible
Blessed are those who are persecuted because of righteousness, for theirs is the kingdom of heaven.
Context
8Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run. 9Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n. 10Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run. 11“Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. 12Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.