Matiu 4:9
Matthew 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”
Matthew 4:9 in English
Matthew 4:9 · Berean Standard Bible
“All this I will give You,” he said, “if You will fall down and worship me.”
Context
7Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” 8Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.” 10Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ” 11Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.