Matiu 4:22
Matthew 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Matthew 4:22 in English
Matthew 4:22 · Berean Standard Bible
and immediately they left the boat and their father and followed Him.
Context
20Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 21Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 23Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.