Native Bible

Matthew 28:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́.

Matthew 28:17 in English

Matthew 28:17 · Berean Standard Bible

When they saw Him, they worshiped Him, but some doubted.

Context

15Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí. 16Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19Nítorí náà, ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.