Native Bible

Matthew 28:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́.

Matthew 28:12 in English

Matthew 28:12 · Berean Standard Bible

And after the chief priests had met with the elders and formed a plan, they gave the soldiers a large sum of money

Context

10Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ” 11Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.