Native Bible

Matthew 28:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.

Matthew 28:11 in English

Matthew 28:11 · Berean Standard Bible

While the women were on their way, some of the guards went into the city and reported to the chief priests all that had happened.

Context

9Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà”, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 10Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ” 11Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.