Native Bible

Matthew 26:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.

Matthew 26:4 in English

Matthew 26:4 · Berean Standard Bible

and they conspired to arrest Jesus covertly and kill Him.

Context

2“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.” 3Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. 4Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. 5Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.” 6Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.