Native Bible

Matthew 26:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Èmi yóò kọlu olùṣọ́-àgùntàn a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’

Matthew 26:31 in English

Matthew 26:31 · Berean Standard Bible

Then Jesus said to them, “This very night you will all fall away on account of Me. For it is written: ‘I will strike the Shepherd, and the sheep of the flock will be scattered.’*

Context

29Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.” 30Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi. 31Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Èmi yóò kọlu olùṣọ́-àgùntàn a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’ 32Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Galili.” 33Peteru sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.