Native Bible

Matthew 25:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe.

Matthew 25:7 in English

Matthew 25:7 · Berean Standard Bible

Then all the virgins woke up and trimmed their lamps.

Context

5Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn. 6“Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’ 7“Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe. 8Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ. 9“Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.