Matiu 24:30
Matthew 24:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.
Matthew 24:30 in English
Matthew 24:30 · Berean Standard Bible
At that time the sign of the Son of Man will appear in heaven,* and all the tribes of the earth will mourn. They will see the Son of Man coming on the clouds of heaven, with power and great glory.*
Context
28Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí. 29“Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,
“ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,
òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;
àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,
agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’ 30“Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. 31Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ. 32“Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.