Matiu 21:9
Matthew 21:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi!” “Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!” “Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
Matthew 21:9 in English
Matthew 21:9 · Berean Standard Bible
The crowds that went ahead of Him and those that followed were shouting: “Hosanna to the Son of David!”* “Blessed is He who comes in the name of the Lord!”* “Hosanna in the highest!”*
Context
7Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. 8Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. 9Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,
“Hosana fún ọmọ Dafidi!”
“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”
“Hosana ní ibi gíga jùlọ!” 10Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?” 11Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.