Matiu 21:33
Matthew 21:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.
Matthew 21:33 in English
Matthew 21:33 · Berean Standard Bible
Listen to another parable: There was a landowner who planted a vineyard. He put a wall around it, dug a winepress in it, and built a tower. Then he rented it out to some tenants and went away on a journey.
Context
31“Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”
Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.” 33“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. 34Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá. 35“Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.