Matiu 21:32
Matthew 21:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”
Matthew 21:32 in English
Matthew 21:32 · Berean Standard Bible
For John came to you in a righteous way and you did not believe him, but the tax collectors and prostitutes did. And even after you saw this, you did not repent and believe him.
Context
30“Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá. 31“Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”
Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.” 33“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. 34Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.