Matiu 21:22
Matthew 21:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”
Matthew 21:22 in English
Matthew 21:22 · Berean Standard Bible
If you believe, you will receive whatever you ask for in prayer.”
Context
20Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnu yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíá?” 21Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀. 22Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.” 23Jesu wọ tẹmpili, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí?” 24Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.