Matiu 2:9
Matthew 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.
Matthew 2:9 in English
Matthew 2:9 · Berean Standard Bible
After they had heard the king, they went on their way, and the star they had seen in the east went ahead of them until it stood over the place where the Child was.
Context
7Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. 8Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.” 9Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. 10Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. 11Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.