Native Bible

Matthew 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.

Matthew 2:7 in English

Matthew 2:7 · Berean Standard Bible

Then Herod called the Magi secretly and learned from them the exact time the star had appeared.

Context

5Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé, 6“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea, ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ” 7Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. 8Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.” 9Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.