Matiu 18:25
Matthew 18:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
Matthew 18:25 in English
Matthew 18:25 · Berean Standard Bible
Since the man was unable to pay, the master ordered that he be sold to pay his debt, along with his wife and children and everything he owned.
Context
23“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì. 25Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà. 26“Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ 27Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.