Native Bible

Matthew 17:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

Matthew 17:6 in English

Matthew 17:6 · Berean Standard Bible

When the disciples heard this, they fell facedown in terror.

Context

4Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” 5Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” 6Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 7Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.” 8Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.