Matiu 17:22
Matthew 17:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.
Matthew 17:22 in English
Matthew 17:22 · Berean Standard Bible
When they gathered together in Galilee, Jesus told them, “The Son of Man is about to be delivered into the hands of men.
Context
19Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” 20Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”* 22Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. 23Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi. 24Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.