Matiu 17:19
Matthew 17:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”
Matthew 17:19 in English
Matthew 17:19 · Berean Standard Bible
Afterward the disciples came to Jesus privately and asked, “Why couldn’t we drive it out?”
Context
17Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” 18Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ. 19Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” 20Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”* 22Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.