Native Bible

Matthew 17:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.”

Matthew 17:12 in English

Matthew 17:12 · Berean Standard Bible

But I tell you that Elijah has already come, and they did not recognize him, but have done to him whatever they wished. In the same way, the Son of Man will suffer at their hands.”

Context

10Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?” 11Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. 12Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” 13Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni. 14Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.