Matiu 17:11
Matthew 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò.
Matthew 17:11 in English
Matthew 17:11 · Berean Standard Bible
Jesus replied, “Elijah does indeed come, and he will restore all things.
Context
9Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.” 10Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?” 11Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. 12Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” 13Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.