Native Bible

Matthew 16:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.”

Matthew 16:6 in English

Matthew 16:6 · Berean Standard Bible

“Watch out!” Jesus told them. “Beware of the leaven of the Pharisees and Sadducees.”

Context

4Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè àmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní àmì bí kò ṣe àmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ. 5Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́. 6Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.” 7Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.” 8Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.