Matiu 13:49
Matthew 13:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo.
Matthew 13:49 in English
Matthew 13:49 · Berean Standard Bible
So will it be at the end of the age: The angels will come and separate the wicked from the righteous,
Context
47“Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja. 48Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè Òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù. 49Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo. 50Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” 51Jesu bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”
Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.