Native Bible

Matthew 13:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.

Matthew 13:45 in English

Matthew 13:45 · Berean Standard Bible

Again, the kingdom of heaven is like a merchant in search of fine pearls.

Context

43Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́. 44“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà. 45“Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. 46Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á. 47“Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.