Matiu 13:43
Matthew 13:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.
Matthew 13:43 in English
Matthew 13:43 · Berean Standard Bible
Then the righteous will shine like the sun in the kingdom of their Father.* He who has ears, let him hear.
Context
41Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́ṣẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú. 42Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà. 43Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́. 44“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà. 45“Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.