Native Bible

Matthew 12:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

Matthew 12:22 in English

Matthew 12:22 · Berean Standard Bible

Then a demon-possessed man who was blind and mute was brought to Jesus, and He healed the man so that he could speak and see.

Context

20Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun. 21Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.” 22Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?” 24Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.