Matiu 11:6
Matthew 11:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”
Matthew 11:6 in English
Matthew 11:6 · Berean Standard Bible
Blessed is the one who does not fall away on account of Me.*”
Context
4Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. 5Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì. 6Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.” 7Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi? 8Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.