Matiu 11:23
Matthew 11:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní.
Matthew 11:23 in English
Matthew 11:23 · Berean Standard Bible
And you, Capernaum, will you be lifted up to heaven? No, you will be brought down to Hades! For if the miracles that were performed in you had been performed in Sodom, it would have remained to this day.
Context
21Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Korasini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní. 24Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.” 25Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.