Native Bible

Matthew 11:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.

Matthew 11:22 in English

Matthew 11:22 · Berean Standard Bible

But I tell you, it will be more bearable for Tyre and Sidon on the day of judgment than for you.

Context

20Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ronúpìwàdà. 21Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Korasini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní. 24Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.