Matiu 11:15
Matthew 11:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́.
Matthew 11:15 in English
Matthew 11:15 · Berean Standard Bible
He who has ears,* let him hear.
Context
13Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó sọtẹ́lẹ̀ kí Johanu kí ó tó dé. 14Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Elijah tó ń bọ̀ wá. 15Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́. 16“Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn: 17“ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín,
ẹ̀yin kò jó;
àwa kọrin ọ̀fọ̀
ẹ̀yin kò káàánú.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.