Malaki 4:2
Malachi 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.
Malachi 4:2 in English
Malachi 4:2 · Berean Standard Bible
“But for you who fear My name, the sun of righteousness will rise with healing in its wings,* and you will go out and leap like calves from the stall.
Context
1“Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn. 2Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso. 3Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4“Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.