Native Bible

Luke 9:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.

Luke 9:6 in English

Luke 9:6 · Berean Standard Bible

So they set out and went from village to village, preaching the gospel and healing people everywhere.

Context

4Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. 5Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” 6Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo. 7Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú, 8Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.