Luku 9:5
Luke 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.”
Luke 9:5 in English
Luke 9:5 · Berean Standard Bible
If anyone does not welcome you, shake the dust off your feet when you leave that town, as a testimony against them.”
Context
3Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. 4Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. 5Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” 6Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo. 7Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.