Native Bible

Luke 8:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.

Luke 8:40 in English

Luke 8:40 · Berean Standard Bible

When Jesus returned, the crowd welcomed Him, for they had all been waiting for Him.

Context

38Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé, 39“Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó. 40Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. 41Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun, 42nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ. Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.