Luku 8:38
Luke 8:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé,
Luke 8:38 in English
Luke 8:38 · Berean Standard Bible
The man whom the demons had left begged to go with Jesus. But He sent him away, saying,
Context
36Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá. 37Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gadara yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó si kúrò. 38Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé, 39“Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó. 40Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.