Luku 6:27
Luke 6:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi, ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín.
Luke 6:27 in English
Luke 6:27 · Berean Standard Bible
But to those of you who will listen, I say: Love your enemies, do good to those who hate you,
Context
25Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,
nítorí ebi yóò pa yín,
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,
nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún. 26Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,
nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké. 27“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi, ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. 28Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. 29Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.