Luku 6:19
Luke 6:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.
Luke 6:19 in English
Luke 6:19 · Berean Standard Bible
The entire crowd was trying to touch Him, because power was coming from Him and healing them all.
Context
17Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn; 18àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́ ni ó sì mú láradá. 19Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá. 20Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní:
“Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì,
nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run. 21Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa
nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò.
Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń
sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.