Luku 4:23
Luke 4:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
Luke 4:23 in English
Luke 4:23 · Berean Standard Bible
Jesus said to them, “Surely you will quote this proverb to Me: ‘Physician, heal yourself! Do here in Your hometown what we have heard that You did in Capernaum.’”
Context
21Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” 22Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?” 23Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ” 24Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. 25Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.