Luku 4:22
Luke 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
Luke 4:22 in English
Luke 4:22 · Berean Standard Bible
All spoke well of Him and marveled at the gracious words that came from His lips. “Isn’t this the son of Joseph?” they asked.
Context
20Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” 22Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?” 23Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ” 24Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.